ORIKI IBADAN

OMO IBADAN KIN NI SOOO RE?

Ibadan mesi Ogo,

nile Oluyole. Ilu Ogunmola,

olodogbo keri loju ogun.

Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya.

Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila.

Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo.

Ibadan Omo ajoro sun.

Omo a je Igbin yoo,

fi ikarahun fo ri mu.

Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,

eyi too ja aladuugbo gbogbo logun,

Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun.

Ibadan Kure!

Ibadan beere ki o too wo o,

Ni bi Olè gbe n jare Olohun.

B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji.

Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu.

Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan.

A ki waye ka maa larun kan lara,

Ija igboro larun Ibadan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

%d bloggers like this: